17/02/2024
*ORO NIPA IBUJOKO FUN OBINRIN*
⚓⚓⚓⚓⚓⚓⚓⚓⚓⚓
⚓ Ẹ fi ara balẹ gbo ọ̀rọ̀ ìṣiti yi, nitori yió ma ṣe wá ni anfani, pàápàá àwa obìnrin.
⚓ ọlọ́gbọ́n kan kò si nibi kankan, àfi Ọlọ́run Ọba lo gbọ́n.
⚓ Bi a ba nsọro nipa ibujoko obinrin, a ńsọro nipa ile ọkọ obinrin ni.
⚓ obinrin ti Ọlọrun bá wa fun ni ibujoko ayọ̀, nitori ọkùnrin gidi tó mọ iyi obinrin, ti o fe o ni iyawo.
⚓ ó yẹ kí iru obinrin bẹ má dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run ni.
⚓ Nitori ọpọlọpọ obinrin, ni nwa iru anfani ti ìwọ ri yi, ṣùgbọ́n ti won ko ri.
⚓ ko si obinrin ti o wu, kò ma wa si nile ọkọ.
⚓ kadara lo ndamu àwọn miran, àwọn obinrin miran si wa, ti ó jẹ́ wipé àfọwọ́fa wọn ni ko je ki won wa Nile oko.
⚓ Ibujoko tí Taye o yàtọ̀ sí ti Kehinde, ṣùgbọ́n ọpọlọpọ obinrin ni wọn nwa ibujoko tí kí n ṣe t**i wọn kakiri.
⚓ ọdọ ọkùnrin tó tí ni
iyawo nile, ni ibujoko obinrin miran wa, tó tí má ni ifọkanbalẹ, ṣùgbọ́n kaka kò fẹ́ ọkùnrin tó tí ni iyawo nile, single lo nwa kiri.
⚓ ọdọ okunrin ti ko ni owo lọ́wọ́ ni ibujoko obinrin miran wá, sugbon olowo lo nwa kakiri lati fẹ́.
⚓ ọdọ ọmọdé kùnrin, bi abile keji tabi abile kẹta ni ibujoko obinrin miran wa, sugbọn a ma claim age, a ní ohun ó lè fẹ́ ọkùnrin ti ohun ju lọ, ni ojo ori, lai mọ̀ wipé, atiyan, ko ni nkankan ṣe pẹ̀lú ọjọ́ orí.
⚓ Ìyàwó akọfẹ Anabi Muhammad (S.W.A)
15yrs logba lọwọ Anabi.
⚓ kò sì aburu ninu re wipe kò fẹ́ okunrin tí ò ju lọ ni ojo ori.
⚓ ohun tó ṣe pataki ni, kí ó ni ayọ̀ ati idunnu ni ibujoko rẹ.
⚓ ọdọ akanda eniyan ni ibujoko obinrin miran wa, sugbon àní ohun kó le fẹ́ alaabọ ara.
⚓ Bi eniyan ba ti ṣíyan lárọ̀ ọjọ́ aye rẹ, ma beru rara.
⚓ iwọ ti Ọlọrun bá wà fun ni oore ọ̀fẹ́, lati ri ọkọ gidi fẹ, má wa tun fi ayọ̀ fọ,
⚓ ṣé jẹjẹ ko si ma gbọọrọ si ọkọ rẹ lẹ́nu,
nitori ibujoko tí ìwọ wa yẹn, omije oju ati awẹ ni àwọn obinrin kan fi nwa.
⚓ bí ìwọ bá wa ni ibujoko ayọ̀, oore nla ni Ọlọ́run se fun ọ, tọju ibujoko rẹ, kí ó ma ba padanu rẹ.
⚓ ko si obinrin ti o wu, tí kò fẹ́ sì nile oko, ri ọkọ rẹ gege bi aláṣẹ rẹ.
⚓ iyin nla àti apọnl