30/05/2025
Torh
Nje bukata odun ileya to ku ojo melo yii lo ko ironu ba iwo?
Fokanbale, Olohun oba wibe-jebe ti fi ase si ewe ati egbo fun eniti o ba mo iwulo re
Aseje asiri yii ni emi ma nje dada bi mo ba ni ojo inawo nla Kan niwaju, pelu ogo Olohun, dandan ni ki n ri owo to ju bukata ohun gan lo 💯
Eja abori nla kan 🐟
Ewe jinwinni 🍀
Ewe etiponola 🍀
Ewe akese 🍀
A o lo gbogbo re papo mo iyere merindinlogun, a o fi se eja abori yii ni epo ati iyo
Bi a ba nse obe yii lowo, a o mu obi oloju merin, a o la, a o fi meji si egbe aro otun, a o fi meji toku si egbe osi t**i a o fi se obe yii tan, bi o ba jinna, a o sokale, a o mu obi yii na kuro, a o wa te eji ogbe sori iyereosun, a o wa daniyan gbogbo ohun ti a nfe sara awon obi yii, a o wa fi awon obi yii si egbe otun ati egbe osi odu na, a o wa pe ohun re sori odu naa
🎤🎤🎤
Olaperi ni awo aiye
Olapesin ni awo ode orun
Aboju 👀 kokoko ko ire wa si aiye loruko ti a npe eyin iya mi aje
E ni kilode ti mo fi npe yin bayii?
Mo ni oju aje lo npon mi ni mo fi npe yin
Nitori inawo ti mo da sile mi o ri owo ma fi se
E ni mo ma ri owo fi se nitemi
E ni ojumo kii mo ki onidikudi ma di egbaa aje ka ori
E ni mo ma ri owo temi, e ni bi okunrin se npe mi ni obinrin yi o ma pe mi si rere
Etiponola mi de abenu ifa lagbo orun
E je ki ara o de mi gbayi, gburugbada ni eja nse lale odo, ara wa demi gbayi o, mo di eni apesin, gbogbo nkan ti mo Fe se yii ni ki n ri se nirorun, iyereosun lo ni ki ire temi ko sun s**o mi
A o wa se adura si obi yii, a o da obi yen, bi o ba yan, a o lo da si orita meta, bi ko ba yan, a o da ifa lori nkan ti o ba fe gba, a o se sara na siwaju ki a to je aseje yii 💯
08103374508